Ìjà abẹnú ADC fẹjú síi, igun kan kẹ̀yìn sí David Mark, yan Dumebi Kachikwu bíi olùdíje ààrẹ, bí igun Mark ṣe fẹ́ yan olùdíje aarẹ lónìí

Lasiko ti wọn n na ọwọ Dumebi Kachikwu soke bii oludije ipo aarẹ ninu ADC ni 2027

Oríṣun àwòrán, ADC

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Igun tuntun kan ninu ẹgbẹ oṣelu African Democratic Congress (ADC), ti lodi si David Mark to jẹ olori ẹgbẹ naa, wọn si ti yan Dumebi Kachikwu bii oludije fun ipo aarẹ ninu ẹgbẹ naa lọdun 2027.

Ana ode yiii ti i ṣe ọjọ Aiku, ọjọ kẹrinlelogun oṣu Karun-un ọdun 2026, ni igun tuntun yi tu igbimọ amuṣẹṣe 'National working committee' (NWC) ti David Mark n dari ka, ti wọn si yan Dumebi Kachikwu lẹyẹ o-sọka.

Eyi ṣọju awọn aṣoju ẹgbẹ, oludije, olori ọdọ atawọn alatilẹyin kaakiri Naijiria ni wọn peju sibẹ.

Nibo leyi ti waye?

Igbesẹ yii waye nibi ipade apapọ ati ibo abẹle si ipo aarẹ igun ADC tuntun ti wọn pe ni ara ọtọ, niluu Abuja.

Nibi ipade ati idibo naa ni awọn aṣoju ẹgbẹ ti fi ohun ẹnu dibo, ti wọn si kede pe Dumebi Kachikwu ni awọn fa kalẹ lati dupo aarẹ ninu ADC ni 2027.

Bi wọn ti ṣe eyi tan ni igun naa yan awọn alabojuto tuntun ti yoo rọpo igbimọ amuṣẹṣẹ David Mark ti wọn tu ka.

Lara awọn alaṣẹ tuntun ti wọn yan ni :

Kingsley Oggah ti wọn fi ṣe Alaga igbimọ olufọkantan, Abdulkadir Bashir; Alaga ẹgbẹ lapapọ, Johnny Derek, Akọwe apapọ ẹgbẹ, Kennedy O. Odion; Akapo apapọ ẹgbẹ, Amirigoye; Akọwe owo ati Chris Ugwu ti wọn fi ṣe oludamọran nipa ofin fun igun ADC naa.

Orita to n daamu alejo ni Naijiria wa, ADC lo le fun wọn ni ireti - Kachikwu

Nigba to n sọrọ lẹyin to gba asia ẹgbẹ AD bii ẹni ti yoo dupo aarẹ, Kachikwu ṣapejuwe Naijiria bii orilẹede ti nnkan ti daru mọ lọwọ.

O ni iṣoro ai si aabo, ai si iṣẹ, ọrọ aje to le koko ati iyapa to n lagbara si i n koju orilẹede yii.

"Gbogbo wa la jọ ni Naijiria, ko si yẹ ko jẹ awọn diẹ to ni anfaani ni yoo maa paṣẹ."

Kachikwu lo ṣalaye bẹẹ.

O fi kun un pe ohun to n ṣẹlẹ lorilẹede yii ti su araalu, o si ti kà wọn laya.

Ọna abayọ si eyi gẹgẹ bo ṣe wi ni ADC, eyi to ni yoo mu ireti ọtun wa fun araalu.

Bakan naa ni Alaga tuntun fun igun ADC yii, Kingsley Oggah, rọ awọn ọmọ ẹgbẹ lati duro ṣinṣin, ki ayipada le de ba Naijiria.

O ni ẹtan ti su awọn ọmọ Naijriia,pelu ajẹbanu ati ileri asan, amọ igun ADC to de yii ni ọjọ iwaju rere ti yoo mu nnkan yipada.

Dumebi Kachikwu yii ni ADC fa kalẹ ni 2023, gẹgẹ bii oludije ipo aarẹ nigba naa, ṣugbọn kadara ko ṣee loore lori rẹ.

Olori ti yoo ṣelu ni Naijiria nilo, ki i ṣe eyi ti yoo kan maa kari ayelujara- Atiku

Ṣaaju ipade apapọ ẹgbẹ oselu ADC , igun ti David Mark ti yoo waye lonii ọjọ Aje, Igbakeji aarẹ nigba kan, Atiku Abubakar, ti sọ fun awon aṣoju ADC pe ki wọn yan ẹni to kunju oṣuwọn fun ipo aarẹ ninu ẹgbẹ wọn.

Ninu atẹjade kan ti Amugbalẹgbẹẹ pataki fun Atiku lori ikede, Phrank Shaibu, fi sita ni Atiku ti ni olori to le dari Naijiria bo ṣe yẹ ni orilẹede yii nilo.

O n ki i ṣe eyi ti yoo kan maa kari ayelujara lori ofo.

Atiku sọ pe ẹgbẹ ADC gbọdọ ri I daju pe oludije to kaju ẹ to si le fidi Tinubu janlẹ ni wọn fa kalẹ.

O ni ẹyi ti yoo ṣẹgun ajẹkun-gbese, ti yoo koju ai si aabo, ti yoo si tun gbogbo ẹka to ti bajẹ ṣe ni ki wọn mu.

Atiku tẹsiwaju pe ki wọn ma ṣe fi ojuṣaaju fa oludije kalẹ, ṣugbọn ki wọn ri I daju pe ẹni to ṣee fiṣẹ ogun ran lawọn gbe ipo naa fun.

Ki lo ṣẹlẹ ṣaaju?

Tẹ o ba gbagbe, rogbodiyan to lagbara lo koju ẹgbẹ ADC ṣaaju, paapaa nigba ti ajọ INEC to n ri si eto idibo, yọ orukọ David Mark ati Rauf Aregbesola kuro lori atẹ wọn.

Ọrọ naa le pupọ ti wọn pada de kootu to ga ju lọ, ti ile ẹjọ si ni ki David Mark maa ba iṣẹ rẹ lọ bii olori ẹgbẹ ADC.

Ko pẹ ko jinna ni awọn eekan to di ẹgbẹ naa mu bii Peter Obi ati Rabiu Kwankwaso kuro ni ADC, ti wọn si lọ darapọ mọ Nigeria Democratic Congress (NDC).

Igun tuntun to gbori jade ninu ADC yii ni ọpọ eeyan ko lero pe yoo waye, ṣugbọn eegun to ba ti jade ti kuro ni a ki i wo o.