Ọwọ́ Amọtẹkun tẹ afurasí agbódegbà àwọn ajínigbé to n múra bíi wèrè l'Ondo

Ikọ Amọtẹkun ipinlẹ Ondo pẹlu ibọn lọwọ wọn

Oríṣun àwòrán, Rotimi Akeredolu Aketi

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Yoruba sọ pe ọjọ gbogbo ni t'ole, ọjọ kan ni ti olohun, bẹẹ gan lọrọ ri fun were kan ti wọn ni o jẹ agbodegba fun awọn ajinigbe ati awọn adigunjale lẹyin ti ọwọ ikọ Amọtẹkun tẹ ẹ tan nipinlẹ Ondo.

Ọga agba ikọ Amọtẹkun nipinlẹ naa, Akogun Adetunji Adeleye lo sọrọ yii lasiko to n foju afunrasi naa lede ni olu ileeṣẹ ajọ ọhun ni Alagbaka niluu Akure.

Adeleye sọ pe wọn ṣe iwadii pẹlu iṣẹ ọtẹlẹmuyẹ eyi to safihan pe awọn ajinigbe yi n mura bii were ki wọn ma baa funra si wọn, ti wọn si n ṣọsẹ jakejado ipinlẹ Ondo.

Oga Amọtẹkun naa ṣalaye pe awọn to n mura bii were yi n lọwọ ninu oriṣiriṣi iwa ibi to fi mọ gbigbe egboogi oloro, ṣiṣe alami fawọn ajinigbe ati awọn adigunjale to fi mọ awọn iwa ko tọ miran.

Báwo ni àwọn Amọtẹkun ṣe mú afunrasí náà?

Ọga agba ajọ Amọtẹkun nipinlẹ Ondo Adetunji Adeleye salaye pe lẹyin iwadii ti wọn ṣe, eyii to fi idi rẹ mulẹ pe awọn ajinigbe yii n mura bii were, wọn bẹrẹ isẹ lati tu iṣu de isalẹ ikoko.

O ṣalaye pe wọn tu awọn ikọ wọn ti ki n wọ aṣọ si igboro lati ṣawari awọn Eniyan naa.

Awọn ikọ naa tọpinpin awọn to mura bii were naa lọ ibi ti wọn ti n fi ina sori ẹrọ ilewọ wọn, ibi ti wọn ti n pawọda, ati ibi ti wọn ti n ṣe ipade lati ṣọsẹ, ki ọwọ to tẹ wọn.

Wọn salaye pe inu ọja ni were ti wọn mu yii ti ń rin kiri lati mọ ẹni ti wọn yoo ṣe akọlu si, ki o to ko si galo awọn Amọtẹkun.

Awọn miran ti wọn tun fi panpẹ ofin gbe

Lasiko to n foju awọn afurasi naa lede Adeleye ṣalaye pe awọn mẹrindinladọrun afunrasi ni wọn fi panpẹ ofin gbe lọwọ yii.

Ọga Amọtẹkun naa ṣalaye pe ọpọlọpọ awọn afurasi naa lọwọ tẹ lasiko ti wọn mu awọn ajinigbe to n ṣọsẹ jakejado ipinlẹ Ondo, ti awọn miran si lọwọ ninu idigunjale, gbigbe oogun oloro ati awọn iwa koto miran lawujọ.

Gẹgẹ bi o ṣe sọ, ọgọta ninu awọn afunrasi naa ni wọn n ṣe ẹjọ wọn lọwọ ni ile ẹjọ, ti wọn si ti yanju awọn ẹsun afunrasi mejidinlogoji to ku lai lọ sile ejọ.