CAN gbé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ orúkọ àwọn èèyàn tí ajínigbé gbé nílé ẹ̀kọ́ mẹ́ta nípínlẹ̀ Oyo jáde, bẹ̀rẹ̀ àwẹ̀ àti àdúrà

Oríṣun àwòrán, Getty Images/CAN
Ẹni to kan lo mọ ni ọrọ ikọlu awọn agbebọn sile ẹkọ mẹta to waye lọsẹ to kọja niluu Ahoro Esinele, Ogbomoso, ipinlẹ Oyo.
Tẹ o ba gbagbe, ninu ikọlu to waye lọjọ Ẹti naa ni wọn ti yinbọn pa olukọ kan lasiko ikọlu, ti wọn si fi fọnran ibi ti wọn ti du olukọ miran bii ẹran sita lọjọ Aiku.
Ninu rẹ naa ni wọn ti ko awọn olukọ ati ọpọ akẹkọọ wọgbo lọ titi di asiko yii.
Wayi, awọn alaṣẹ ti fi orukọ awọn eeyan to wa nigbekun awọn ajinigbe agbebọn naa lede ninu eyi ti ọmọdebinrin kan ti ọjọ ori rẹ ko ju ọmọ ọdun meji lọ wa.
Eeyan mẹrindinlaadọta (46) ni a gbọ pe wọn gbe lọ. Olukọ meje ati akẹkọọ mọkandinlogoji (39) ni wọn.
Awọn ile ẹkọ mẹta ti wọn ti ko wọn lọ ni:
Community High School Ahoro-Esinele, Yawota Baptist Nursery and Primary School ati ile ẹkọ alakọọbẹrẹ LA.
Orukọ awọn olukọ ti wọn gbe lọ ni Community High School, Ahoro Esinele:
1 Abilekọ Alamu Folawe – Ọga agba ile ẹkọ
2. Ọgbẹni Ojo Jonathan – Igbakeji ọga agba
3. Ọgbẹni Olatunde Zacchaeus – Olukọ
4. Ọgbẹni John Olaleye – Olukọ
5. Ọgbẹni Michael Oyedokun–(Olukọ ti wọn fi fidio bi wọn ṣe du u lọrun si ori ayelujara).
6. Abilekọ Oladeji –Olukọ
7. Mary Akanbi – Olukọ ni Yawota Baptist Nursery and Primary School.
Awọn akẹkọọ lati Ahoro Esinele
8. Rashida Tajudeen – ọmọ ọdun mọkanla
9. Ahmed Ramoni – ọmọ ọdun mẹjọ
10. Abdulsalam Toyib – ọmọ ọdun mẹrin
11. Baraka Abioye – ọmọ ọdun mẹrindinlogun
12. Fatimo Jimoh – ọmọ ọdun mẹẹẹdogun
13. Hassan Azeez – ọmọ ọdun mẹrinla
14. Joshua Adeleke – ọmọ ọdun mẹtala
Awọn ti wọn gbe lọ lati Yawota:
15. Samuel Oyedele – ọmọ ọdun meje
16. Emmanuel Oyedele – ọmọ ọdun mẹrin
17. Idowu Taiwo – ọmọ ọdun mẹrin
18. Christianah Akanbi – ọmọ ọdun meji
19. Juwon Sunday – ọmọ ọdun meje
20. Sikiru Salami – ọmọ ọdun mẹta
21. Soliu Salami – ọmọ ọdun mẹrin
22. Ojo Joseph – ọmọ ọdun mẹjọ
23. Lydia Adewole – ọmọ ọdun mẹjọ
24. Testimony Jacob – ọmọ ọdun marun-un
25. Kehinde Kaosara – ọmọ ọdun meje
26. Sewa Seyi – ọmọ ọdun meje
27. Waliya Bello – ọmọ ọdun mẹrin
28. Lydia Olohunloluwa – ọmọ ọdun meje
29. Damilare Oderinde – ọmọ ọdun mẹjọ
30. Deborah Adebowale – ọmọ ọdun marun-un
31. Aisha Oguntowo – ọmọ ọdun mẹwaa
32. Lege Taiwo – ọmọ ọdun mejila
33. Balkis Ayanwale – ọmọ ọdun mẹjọ
34. Asa David – ọmọ ọdun mẹwaa
Awọn ti wọn ji gbe lọ lati adugbo Oniya
35. Shuaibu Aliyu – ọmọ ọdun mẹwaa
36. Ahmed Aliyu – ọmọ ọdun meje
37. Muiz Aliyu –ọmọ ọdun marun-un
38. Jomiloju Ogunlola – ọmọ ọdun mẹfa
Awọn ọmọ agbegbe Alawusa:
39. Agune Noah – ọmọ ọdun mẹjọ
40. Elizabeth Abadi – ọmọ ọdun marun-un
41. Tosin Abadi – ọmọ ọdun mẹsan-an
42. Pius Stephen – ọmọ ọdun marun-un
43. Hannah Ojo – ọmọ ọdun mẹrinla
44. Habidat Ayanwale – ọmọ ọdun meje
45. Mary Gabriel – ọmọ ọdun mẹfa
46. Jacob Gabriel – wọn ko sọ ọjọ ori rẹ.
Ajọ CAN kede aawẹ ati adura lori ọrọ yii
Tẹ o ba gbagbe, Ọjọruu ti I ṣe ọgunjọ oṣu Karun-un ọdun 2026 yii ni ajọ onigbagbọ lorilẹde Naijiria, ẹka ti ipinlẹ Oyo, ya sọtọ fun awọn ileejọsin kaakiri ipinlẹ Oyo lati fi gba aawẹ ati adura.
CAN kede eyi pẹlu alaye pe kawọn eeyan to wa nigbekun le gba itusilẹ ni.
Ninu atẹjade ti Alaga wọn, Ẹni ọwọ Elisha Ogundiya fi ṣọwọ si ajọ akoroyinjọ Naijiria (NAN), niluu Ibadan lọjo Aje ni won ti kede eyi.
Ẹgbẹ onigbagbọ naa fi aidunnu rẹ han si iṣẹlẹ yii, wọn si ni ki aawẹ ati adura waye lọjọ naa ti I ṣe Ọjọru ana.
Aago mẹfa irọlẹ ni CAN kede pe kawọn eeyan ṣinu aawẹ ọhun.
Bakan naa ni won rọ ijọba lati ji giri si wahala yii, nitori ohun toju awon ẹni to wa nigbekun laiṣẹ naa yoo maa ri ko ṣee ronu rẹ rara.


























