Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́
Awọn afurasi agbebọn ṣekọlu si agboole ile igbe kan ni ilu Ijebu-Ode, ipinlẹ Ogun
Nibi ti wọn ti ji eeyan mẹta ti igbagbọ wa pe wọn jẹ ẹbi kan naa, gbe lọ.
Iroyin ni nnkan bii aago meje irọlẹ lawọn afurasi agbebọn naa to mẹẹdogun yabo ibugbe Ipojo Golden Estate
Ileeṣẹ ọlọpaa Ogun ni iwadii ti bẹrẹ lori iṣẹlẹ naa
Ka a loju opo wa
xxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxx
O ṣe, o doju ala, a tun di bi eni ba jọni
Gbajumọ oṣere tiata, Alex Ekubo dagbere faye leni ogoji ọdun
Irọlẹ ọjọ Iṣẹgun ni iroyin iku gbode, tawọn akẹgbẹ rẹ si n kọrin aro lẹyin rẹ
Bi o tilẹ jẹ pe ẹbi Alex ko i tii sọrọ tabi fidi ohun to pa a mulẹ
Iroyin to gbode ju ni pe Jẹjẹrẹ inu Kindinrin lo mu Alex Ekubo lọ.
Ẹkunrẹrẹ iroyin nipa jejẹrẹ kindinrin wa ni bbcnews.com/yoruba
xxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxx
Mi o ni kọwe fipo silẹ
Olootu ijọba ilẹ Gẹẹsi, Sir Keir Starmer lo fariga bẹẹ lẹyin tawọn alatako rẹ n pe fun ikọwefiposilẹ rẹ.
Ki lo de ti wọn ko kọwe fipo silẹ gan?