Èèmọ̀ dé! Èyí làwọn bàbá tó ń ta ọmọ gbowó nítorí àti jẹun

Oríṣun àwòrán, Imogen Anderson/BBC
- Author, Yogita Limaye
- Role, South Asia and Afghanistan correspondent
- Published
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 8
Bi ojumọ ṣe n mọ, ọpọ awọn ọkunrin to si ẹsẹ titi ni Chaghcharan, olu ilu Ghor ni Afghanistan.
Wọn to si ẹsẹ titi naa ti oju wọn si kọrẹ lọwọ, pẹlu erongba pe eeyan kan maa muṣẹ wa fun wọn. Eyi lo maa sọ boya wọn maa jẹun nile lọjọ naa.
Amọ ati ri iṣẹ ṣe wọn ko daju.
Juma Khan, ẹni ọdun marundinlaaadọta ṣẹṣẹ ri iṣẹ ọjọ mẹta ṣe lati ọsẹ mẹfa sẹyin eyi ti owo to ri nibẹ jẹ 150 si 200 owo Afghanistan ($2.35-$3.13; £1.76-£2.34) lojumọ kan.
"Awọn ọmọ mi ko jẹun sun ni ọjọ mẹta lera wọn. Iyawo mi kan n sunkun ni, bẹẹ naa ni awọn ọmọ mi. Fun idi eyi, mo tọrọ owo lọwọ alabagbemi lati fi ra iyẹfun ni.
"Niṣe ni ẹru maa n bami ni gbogbo igba pe ṣe ebi o ni pa awọn ọmọ mi ku."
Ohun to n ṣẹlẹ si Khan yii kii ṣe ohun nikan lo n ṣẹlẹ si.
Ikilọ: Iroyin yii ni awọn nnkan to le ba eeyan lọkan jẹ
Ni Afghanistan lonii, eeyan mẹta ninu eeyan mẹrin ni ko ni ohun ti wọn n fẹ lati fi gbe aye gẹgẹ bi ajọ iṣọkan agbaye ṣe sọ. Airi iṣẹ ṣe gbilẹ, eto ilera ko rẹsẹ mulẹ, ti adinku si ti ba awọn ajọ to n ṣe iranwọ fawọn eeyan nibẹ.
Orilẹ ede naa lo n koju ebi to lagbara, bi eeyan miliọnu marun-un din diẹ ni iwadii ni wọn ku diẹ ki wọn wa ninu iyan.
Ghor wa lara awọn ibi to n koju ebi to lagbara .
"Mo gba ipe pe awọn ọmọ mi ko i tii jẹun fun ọjọ meji, Rabani sọ pẹlu ohun gbigbọn.
"Niṣe lo dabi ki n para mi ṣugbọn mo ro o pe bawo lo ṣe maa jẹ iranwọ fun ẹbi mi, idi niyẹn ti mo fi wa nibi lati wa iṣẹ."

Oríṣun àwòrán, Imogen Anderson/BBC
Kwaja Ahmed ko i tii sọrọ pupọ to fi bẹrẹ si ni sunkun.
"Ebi n pawa. "Ọmọ mi to dagba ti jade laye, mo nilo lati ṣiṣẹ lati fun awọn ẹbi mi lo n jẹ ṣugbọn mo ti dagba, ko si ẹni to fẹ gbeṣẹ fun mi."
Nigba ti ileeṣẹ burẹdi to sunmọ titi naa ṣẹṣẹ ṣi, eni to ni ileeṣẹ naa maa n pin burẹdi to ba ti pẹ fun wọn. Laaarin iṣẹju aaya ni wọn maa pe bo o, ti onikaluku maa ma sare lati mu fun ẹbi wọn.
Ọkunrin kan gun ọkada lati fẹ wa mu ẹnikan lati ba a ko bulọọku ikọlu ikọle, ọpọ wọn lo sare sii.
Fun wakati meji ti a lo nibẹ, eeyan mẹta pere lo ri eeyan pe wọn fun iṣẹ.
Ni ilu kan to sunmọ ibẹ, Abdul Rashid Azimi mu wa lọ sile rẹ, to si fi awọn ibeji rẹ, awọn ọmọ ọdun meje, Roqia ati Rohila han wa lati ṣalaye idi to fi n ṣe ohun to n ṣe.
"Mo ṣetan lati ta awọn ọmọ mi," ó sunkun. "Mi o lowo, mo jẹ gbese, mi o ni oluranlọwọ.
"Ete mi gbẹ bọ lati ibiṣẹ, ebi n pami, ko si omi, ko si ounjẹ. Awọn ọmọ mi ni ki n fun awọn ni burẹdi amọ ki ni mo ri fun wọn, iṣẹ da?"
Abdul ni oun ṣetan lati ta awọn ọmọbinrin naa fun igbeyawo tabi lati lọ ṣiṣẹ ọmọ ọdọ. O ni ti oun ba ẹyọkan ninu wọn, oun maa lowo lati fi bọ awọn yooku fun bii ọdun mẹrin.
O ni oun to ba oun lọkan jẹ ni amọ ọna kan ṣoṣo ti oun ni niyẹn.

Oríṣun àwòrán, Imogen Anderson/BBC
"Ohun kan ti a maa n ri jẹ ni burẹdi ati omi gbigbona, a kii ri tii," iya wọn Kayhan sọ.
Ipinnu lati ta ọmọbinrin dipo ọmọkunrin ni Afghanistan ko ṣẹyin pe wọn maa n ri awọn ọmọkunrin bii eni to le pese fun idile lọjọ iwaju, to si jẹ pe ijọba Taliban ko fi aaye gba awọn ọmọbinrin lati ṣiṣẹ tabi lọ sile ẹkọ.
Bakan naa ni aṣa fifun awọn idile obinrin lẹbun lati idile ọkọ nigba ti ọmọbinrin ba n lọ sile ọkọ.
Awọn ọmọ Abdul meji ti wọn ti dagba diẹ n ṣiṣẹ siso bata laaarin ilu, ọkan maa n ṣalẹ ti Kayhan maa n lo lati fi dana.
Saeed Ahmad sọ fun wa pe oun ta ọmọbinrin oun, ọmọ ọdun marun-un, Shaiqa nigba ti oun nilo lati ṣiṣẹ abẹ nitori ailera ti ọmọ naa ni ninu ẹdọ.
"Mi o ni owo ti maa fi san owo ile iwosan, nitori naa mo ta ọmọ mi fun ibatan kan."
Iṣẹ abẹ Shaiqa lọ deedee. Lara owo to ta ọmọ naa lo fi sanwo nile iwosan.
"To ba jẹ pe mo gba gbogbo owo nigba naa, o ti maa mu ọmọ mi lọ amọ mo gba nnkan t imo nilo lati fi sanwo nile iwosan, m oni ko fun mi ni iyoku lẹyin ọdun marun-un ko wa mu ọmọ nigba naa."
O tumọ si pe lẹyin ọdun marun-un, ti Shaiqa maa pe ọdun mẹwaa lo maa lọsile eni ti wọn ta a fun, to si maa lọ ṣe iyawo ọkan ninu awọn ọmọ ẹni naa.
O ni ti oun ba lowo, oun ko nig be igbesẹ bẹẹ amọ oun ro o pe ti oun ko ba ṣe bẹẹ ti ọmọ naa ba lọ ku nkọ?
Iwa fifi ọmọde lọkọ gbile ni Afghanistan, to si n peleke si nitori bi ijọba Taliban ṣe fofin de awọn ọmọbinrin lati ma lọ sile ẹkọ.

Oríṣun àwòrán, Imogen Anderson/BBC
Ni bii ọdun mejhi sẹyin, Saeed maa n ri iranwọ ounjẹ, ororo, awọn oogun ọmọde latọwọ awọn ajọ to maa n ṣe iranwọ fawọn orilẹ ede.
Amọ bi adinku ṣe ti ba ohun tawọn ajọ yii n pese ti ṣakoba fun ọpọ awọn idile ti wọn gbọkan le aanu yii.
Orilẹ ede Amẹrika - to wa lara awọn to maa n pese iranwọ gidi fun Afghanistan – mu adinku to loorin ba iranwọ ti wọn n ṣe fun Afghanistan lọdun to kọja. Ọpọ awọn to maa n ṣe iranwọ bẹẹ lo tun mu adinku ba iranwọ ti wọn n ṣe to fi mọ UK.
Iwadii UN ṣafihan pe iranwọ ti wọn ri gba ni ọdun yii ni adinku ti ba fun bii ida aadọrin si ohun ti wọn ri lọdun 2025.
Ọgbẹlẹ, to ti ṣakoba fun ohun to le ni ilaji gbogbo orilẹ ede naa wa lara ohun to n ṣakoba fawọn eeyan.
Taliban, ti wọn fi agbara gbajọba lọdun 2021 n di ẹbi ru ijọba to kuro lori ipo, eyi to mu kawọn Ologun lati ilẹ okeere kuro ni orilẹ ede naa.
"Fun bii ogun ọdun ti wọn fi wa lori ipo, wọn ko ọpọ dọla Amẹrika wọle," Hamdullah Fitrat, to jẹ igbakeji agbẹnusọ ijọba Taliban sọ fun BBC.
Fitrat sọ pe ijọba awọn jogun iṣẹ, oṣi, aisi iṣẹ atawọn iṣoro mii lọwọ ijọba to gbesẹ.
Sibẹ, awọn ofin ti ijọba to wa lori ipo n ṣe paapaa fifi ofin tako awọn obinrin wa lara ohun to n le awọn to n pese iranwọ fawọn orilẹ ede naa.
Amọ ijọba Taliban ni awọn ko lọwọ ninu idi tawọn ajọ to n pese iranwọ fawọn eeyan ko ṣe ṣe bẹẹ mọ.
Fitrat darukọ awọn igbesẹ ti ijọba Taliban n gbe lati mu adinku iṣẹ ati pipese iṣẹ to fi mọ awọn ohun amayedẹrun ati akanṣe iṣẹ iwakusa.
Bi o tilẹ jẹ pe awọn igbesẹ yii le pada so eso rere lọjọ iwajau, o han gbangba pe ọpọ awọn eeyan ni ko ni le bori ebi to n bawọn finra bayii ti asiko naa fi maa de.
Awọn eeyan bii Mohammad Hashem ti ọmọ rẹ, ọmọ oṣu merinla jade laye ni bii ọse diẹ sẹyin nitori airi ounjẹ jẹ ati riri ogun lo.
Agbalagba kan ni agbegbe naa ni awọn ọmọde to n ku latari airi ounjẹ jẹ lo ti pọ si bayii.
Bi o tilẹ jẹ pe ko si akọọlẹ lati fidi iye eeyan to tik u mulẹ, ohun ti a ṣe ni lati ka saare awọn eeyan to ti ku, to si fi han pe bi ọmọde ṣe n ku naa lawọn agba naa n ku.

Oríṣun àwòrán, Imogen Anderson/BBC
Awọn ẹri to foju han wa ni ile iwosan ni Chaghcharan.
Ẹka to wa fun awọn ọmọ ti wọn ṣẹṣẹ bi ni o kun julọ. Niṣe ni gbogbo bẹẹdi kun, awọn mii, ọmọ meji lo wa lori ibusun kan.
Nọọsi kan yi awọn ibeji ti wọn ṣẹṣẹ bi wọle, oṣu wọn ko pe, ọkan wọn kilogiraamu meji, nigba ti ikeji wọn kilogiraamu kan ṣoso.
Ara iya awọn ọmọ naa ko fi bẹẹ le nitori ko fi bẹẹ ri ounjẹ nigba to wa ninu oyun awon ọmọ naa. Burẹdi ati tii nikan lo ri jẹ gẹgẹ iyaiya awọn ọmọ naa ṣe sọ.
Lẹyin wakati diẹ ti a kuro nile iwosan ni ọmọ eyi to gbewọn to pọ jade laye ti iyaiya si n ni ireti pe ọmọ kan yooku maa ye.

Oríṣun àwòrán, Imogen Anderson/BBC
Nọọsi Fatima Husseni sọ pe ọmọ mẹta le ku lọjọ kan ṣoṣo nigba mii.
"O jẹ ohun to le fun mi lati gba mọra nigba t imo kọkọ bẹrẹ iṣẹ ti mo ri bi awọn ọmọ ṣe n ku amọ o ti mọra bayii," o sọ.
Dokita Muhammad Mosa Oldat to n ṣe amojuto ẹka naa sọ pe bi awọn ọmọde ṣe n ku ti wọ bii id aida mẹwaa, ohun to ni o buru jai.
Amọ to ni iṣẹ to n ba awọn eeyan finra, niṣe ni awọn alaarẹ n pọ si ni ojoojumọ, ti wọn ko si ni ohun elo lati tọju awọn ọmọ naa bo ṣe yẹ.
Ni ẹka itọju awọn ọmọ to lagbara, ọmọ ọwọ, ọmọ ọsẹ mẹfa, Zameer n koju aisan yinrunyinrun ati pneumonia. Awọn aisan mejeeji lo ṣe e tọju amọ wọn nilo lati ṣe ayẹwo MRI amọ ko si ohun elo lati fi ṣe.
Ohun to jẹ iyalẹnu julọ ni pe awọn nọọsi naa sọ pe ile iwosan ijọba ko ni ogun to maa fun awọn alaarẹ, tawọn eeyan si maa n ra ogun funra wọn.
Nọọsi Fatima ni ogun tawọn ti wọn ba lowo ba lo ku ni awọn maa n lo fun ẹlomii.
Aisio wo n jẹ kawọn ẹbi ṣe ipinnu to lagbara, ti wọn si maa n gbe awọn eeyan wọn lọ sile nigba ti ko ba si owo mọ.
Awọn ebi Zameer gba pada sile nitori aisi owo, ti wọn si gbe ibeji kan yooku naa lọ sile leyin ti mimi rẹ ṣe diẹ, to si bu sara diẹ si.
Afikun iroyin latọwọ Imogen Anderson, Mahfouz Zubaide ati Sanjay Ganguly


























