Saheed Osupa, gbajúmọ̀ akọrin fuji ti pariwo síta lórí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n jí gbé l'Ogbomoso; ohun tó sọ rèé

Osupa Saheed wọ ẹwu funfun ati fila, o si mu gbohungbohun lọwọ

Oríṣun àwòrán, King Saheed Osupa/Instagram

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Gbajugbajaa akọrin Fuji, Saheed Osupa, ti kepe ijọba lati doola awọn akẹkọọ ati olukọ ti wọn ji gbe ni Esinele ati Yawota nijọba ibilẹ Oriire l'Ogbomoso ni kiakia.

Lọjọ kẹẹdogun oṣu Karun un to kọja lawọn janduku agbebọn yabo ile ẹkọ girama Esinele ati ile ẹkọ alakọbẹrẹ ijọ Onitẹbọmi Baptist Nursery and Primary School ni Yawota nibi ti wọn ti ji eeyan to le logoji gbe.

Ọrọ ijinigbe naa ti di nnkan ti ọpọ eeyan n sọ nipa rẹ bayii papaa julọ lẹyin tawọn agbebọn naa ṣe afihan fidio ọkan lara awọn olukọ ti wọn ji gbe, Michael Oyedoku, eyi ti wọn ti bẹ ori rẹ.

Fidio ọga ile ẹkọ girama Esinele, Arabinrin Rachael Alamu, nibi to ti n bẹ ijọba atawọn lajọlajọ lati doola awọn to wa lakata ajinigbe naa tun ti jẹ kawọn eeyan tun maa sọ nipa iṣẹlẹ naa.

Arabinrin Alamu rọ ijoba wi pe ki won ma lo ipa tori awọn agbebọn naa ti fẹ pa ẹlomiran ninu awọn.

O ni ki wọ bawọn janduku naa sọrọ ni itubi inubi.

Ninu ọrọ rẹ, Osupa fi orin kepe ijọba wi pe ki wọn sa gbogbo apa wọn lati doola awọn akẹkọọ naa.

''Ijọba gbọdọ doola awọn akẹkọọ ti wọn ji gbe ni kiakia, tori awọn obi wọn ko jẹ anfaani orilẹede yii,'' Oṣupa lo sọ bẹẹ.

Ọpọ ọmọ Naijiria lo ti sọ pe ọrọ gidi ni gbajumọ olorin naa sọ, ti awọn naa si n pe fun itusilẹ awọn ọmọ ile ẹkọ atawọn olukọ wọn ti wọn wa lakata ajinigbe ọhun.

Skip Instagram post
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Instagram post

Aráàlú fárígá, àwọn olùwọ́de já géètì sẹkitéríàtì ìjọba, ìpè fún ìtúsílẹ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ àti olùkọ́ tí wọ́n jí gbé l'Ogbomoso káàkiri Nàìjíríà

Awọn oluwọde to n pe fun itusilẹ awọn akẹkọọ ati olukọ ti wọn ji gbe l'Ogbomoso

Awọn oluwọde to n pe fun itusilẹ awọn akẹkọọ atawọn olukọ ti wọn ji gbe l'Ogbomoso ti ja geeti olu ileeṣẹ ijọba ipinlẹ Ogun to wa l'Abeokuta wọle.

Awọn eeyan naa ti wọn ko ara wọn lati fi aidunnu wọn han si bawọn eeyan naa ṣe wa ni akata awọn ajinigbe lati ọjọ kẹẹdogun oṣu Karun un ti kọja, bẹnu ẹtẹ lu bi ijọba ko ṣe tii ri wọn doola.

Titi pa ni geeti olu ileeṣẹ ijọba naa nigba ti wọn de ibẹ, eyi lo si jẹ ki wọn fi ipa ṣi geeti naa wọle lati le fi aidunnu wọn han si ijọba.

Ọpọ eeyan lo ti pin fidio ifẹhonuhan naa kaakiri ori itakun ayelujara.

Ni ipinlẹ Osun, ẹgbẹ awọn olukọ ẹka ti ipinlẹ naa dara pọ mọ iwọde to n lọ lati pe fun itusilẹ awọn akẹkọọ atawọn olukọ to wa ni akata awọn ajinigbe.

‎Ifẹhonuhan naa lo waye ni ilu Osogbo to si gbera sọ ni deede agogo mẹwaa ku iṣẹju mẹsan an.

Iwọde naa bẹrẹ lati agbegbe Ataoja ti wọn si gbe e wọ inu ọfiisi ijọba ni Abere.

‎Pẹlu oju kikoro ati omije loju ni awọn olukọ naa fi ṣe iwọde naa ti orin aro si n jade lẹnu wọn bi wọn ṣe n ṣe iwọde naa lọ.

Awọn oluwọde naa kepe ijọba Aarẹ Bola Ahmed Tinubu ati ijọba gomina Ademola Adeleke lati pasẹ aabo to peye fun olukọ ati akẹkọ paapa fun gbogbo ara ilu.

''Bi ko ba si aabo fun wa, a ti ṣe tan lati bẹrẹ iyanselodi.

‎A fun ijọba apapọ ati ijọba ipinlẹ Ọyọ ni ọjọ meje pere lati gba awọn akẹkọọ ati olukọ to wa ni akata awọn ajinigbe ni ipinlẹ Ọyọ silẹ.''

''Iyanṣẹlodi wa yoo tẹwsiwaju ti ijọba ko ba doola awọn akẹkọọ atawọn olukọ to wa lakata ajinigbe''

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

‎Babatunde Babalola, ẹni to jẹ alaga fun ẹgbẹ awọn olukọ ẹka ti ipinlẹ Osun, ti bu ẹnu atẹ lu bi ko ṣe si eto aabo to peye ni orile-ede Naijiria lọwọlọwọ bayii ati bi ipaniyan ati ijinigbe ṣe di lemọ lẹmọ.

‎Alaga naa wa sọ eyi daju pe, bi ijọba apapọ ati ijọba ipinlẹ Ọyọ ko ba wa ọna abayọ lati gba awọn akẹkọọ ati olukọ ti awọn ajinigbe ko lọ ni Ogbomoso si lọ, awọn ṣe tan lati bẹrẹ iyanselodi.

‎Alaga naa wa rọ gbogbo awọn olukọ ati akẹkọọ ki wọn wa ni oju ni alakan fi sọri ni gbogbo igba ati wi pe, ki onikaluku maa dira ogun ni gbogbo igba.

‎Muritala Jimoh, ẹni to jẹ akọwe fun ile-iṣẹ to ri si eto ẹkọ ni ipinlẹ Osun lo soju gomina Adeleke lati ba awọn olukọ ti wọn ṣe iwọde ifẹhonuhan lori eto aabo to mẹhẹ sọrọ.

‎Ninu ọrọ to ba awọn olukọ naa sọ lo ti sọ pe, gbogbo awọn ẹsọ alaabo to wa ní ipinlẹ Osun ni gomina Adeleke ti ba ṣe ipade lori bi aabo yoo ṣe wa fun gbogbo olugbe ipinlẹ Osun paapaa julọ awọn olukọ ati akẹkọ.

‎ Ẹgbẹ olukọ Ipinlẹ Ọyọ pẹlu ifowosowopo naa ṣe bẹrẹ iwọde tako ijinigbe àwọn akẹkọọ àti olùkọ ti awọn ajinigbe jigbe ni ilu Ogbomoso.

Ẹgbẹ olùkọ ẹka Ipinlẹ Ondo darapọ mọ àwọn ojugba wọn lati se iwọde tako ijinigbe àwọn akẹkọọ àti olùkọ ni Esinele ati Yawọta l'Ogbomoso.

Ẹgbẹ olùkọ Ipinlẹ Kwara naa bẹrẹ iwọde tako ijinigbe àwọn akẹkọọ àti olùkọ Yawọta ni Ogbomọshọ