Àwọn wo ló fẹ́ wú ère ẹlẹ́sẹ̀ ayò, Lionel Messi, àti pé kí ló fàá?

Ere Messi to wa igboro India

Oríṣun àwòrán, gettu images

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ijọba orilẹede India ti kede pe oun yoo gbe ere Lionel Messi to ga ni iwọn aadọrin bata kuro nibi to wa lẹyin to bẹrẹ si n mi logbo-logbo lẹyin iji kan.

Ere giga naa to wa ni Kolkata, ni West Bengal ni wọn gbe kalẹ ninu oṣu Kẹwaa ti Messi rinrinajo 'GOAT' lọ sorilẹede ọhun.

Awọn ileeṣẹ iroyin abelẹ jabọ pe awọn oṣiṣẹ ajọ Public Works Department (PWD) ti lọ ṣayẹwo ere ọhun lẹyin ti awọn araalu fi ọrọ naa to wọn leti.

Wọn ni ijọba paṣẹ ki wọn gbe ere naa ti wọn ṣakiyesi pe ipinlẹ rẹ ti n yẹ.

Aṣofin to n ṣoju iwọ oorun Bengal, Sharadwat Mukherjee sọ fun awọn akọroyin pe "Ere agbabọọlu Argentina naa lewu nibi to wa.

"A ṣakiyesi pe ere ọhun n mi lasiko ti atẹgun ba n fẹ."

Mukherjee fi kun pe yoo rọrun lati wu ere naa kuro nibi to wa latari pe o sunmọ oju ọna ti ọpọ ọkọ n gba kọja ati oju ọna reluwee abẹ ilẹ, ati pe asiko ti anfani ba ti yọ lawọn gbe ere naa kuro.

Ileeṣẹ iroyin abẹle kan sọ pe gbogbo ohun to yẹ lawọn ti ṣe lati daabo awọn eeyan to wa nitosi lasiko ti wọn ba n gbe ere naa kuro nibi to wa lọwọ yii ki awọn eeyan ayika ma baa farapa.

Awọn alaṣẹ ti n ronu nipa agbegbe mii ti wọn le gbe ere naa lọ si bayii.

Messi jẹ ọkan lara awọn agbabọọlu to ta lẹnu julọ kaakiri agbaye lẹyin to ti ṣe ọpọ aṣeyọri lasiko to n gba bọọlu fun Argentina ati oniruru ẹgbẹ agbabọọlu mii to ṣiṣẹ fun.