Àlàyé rèé lórí bí àwọn aṣọ́bodè ṣe gba bọ́ọ̀sì tó kún fún aṣọ ológun àti òògùn olóró tówó rẹ̀ tó ₦259.68m l'Ogun

Ọkọ akero naa, awọn tọwọ ba atawọn nnkan ti wọn ba ninu ọkọ

Oríṣun àwòrán, Ogun Area 1 Custom

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Obitibiti aṣọ ologun ilẹ wa Naijiria ati oogun oloro ti iye rẹ to ₦259.68 ni awọn ẹṣọ aṣọbode ti gba bayii lọwọ awọn ọkunrin meji kan nipinlẹ Ogun, eyi ti wọn ko sinu bọọsi akero kan.

Oju ọna marosẹ Sagamu–Ore–Benin, ni ọwọ ti ba awọn ọkunrin meji naa lọjọ Aiku ọsẹ yii, gẹgẹ bi awọn aṣọbode ẹkun Ogun Area 1 ṣe sọ.

"Aago kan aabọ oru lọwọ ba wọn, lasiko ti wọn n lọ si ilẹ Igbo"

Adele ọga agba ẹka ileeṣẹ aṣọbode agbegbe nipinlẹ Ogun, Oladapo Afeni, ṣalaye bo ṣe ṣẹlẹ.

Ọga kọstọọmu naa sọ pe nnkan bii aago kan aabọ oru ọjọ Aiku naa ni mọto to ko awọn ẹru ofin ọhun de, o ni mọto naa ko ni nọmba idanimọ kankan.

Ileeṣẹ ọlọkọ ero kan ni Afeni sọ pe o ni ọkọ ọhun.

Nigba to n tẹsiwaju ninu alaye rẹ fun awon oniroyin lọjọ Aje, n'Idiroko, ọga Aṣọbode Ogun naa sọ pe:

"Olobo lo ta wa lori ọkọ naa ta a fi bẹrẹ si I tọpinpin rẹ lati Eko, to si gba ọpọ ibi ayẹwo kọja ka too mu un l'Ogun."

"Awọn ohun ti a ba ninu ọkọ naa"

Afeni ṣalaye pe bawọn ṣe tu ọkọ naa kalẹ jẹ kawọn ri ọpọ ohun to lodi sofin ti wọn ko sinu rẹ.

Lara ohun ti ọga aṣọbode naa sọ pe awọn ri ni aṣọ ologun mẹtadinnigba (197) ti wọn jẹ ṣokoto gigun ati penpe.

Inu awọn paali lo ni wọn di wọn si, ti wọn si di I lọna ti eeyan ko fi le fura si ohun to wa ninu rẹ.

Bakan naa ni wọn tun di awon aṣọ ologun yii to pé lodidi pẹlu ewu ati ṣokoto, awọn jẹ marun-un.

Aṣo awọtẹnu ologun mejilelọgbọn (32), aṣọ ologun ti wọn maa n wọ sita bii polo; mejilelọgbọn atawọn nnkan elo ileeṣẹ ologun miran ni awọn aṣọbode tun ri pẹlu.

Ni ti oogun oloro, Ọga aṣọbode yii sọ pe awọn ri idi mẹrinlelaaadọjọ (154), iyẹn oogun naa ti a mọ si Loud.

Ìdì meje "Colorado," toun naa jẹ oogun oloro, ti wọn ko pamọ sinu ọkọ naa ni wọn tun ri pẹlu.

Ki ni wọn fẹ fi awọn aṣọ ologun naa ṣe?

Gẹgẹ bi Afeni ṣe wi, o ni iwadii fi han pe awọn afurasi ẹda naa fẹ pin awọn aṣọ ologun wọnyi fun awọn ti ko lẹtọọ lati wọ ọ ni, ti wọn yoo sọ ara wọn di ayederu sọja.

O ni o si ṣee ṣe ki wọn maa lo o lati fi huwa aburu ti yoo tun mu iwa ọdaran peleke si i.

"Akojọpọ oogun oloro ati aṣọ ologun ninu ọkọ kan naa n tọka si igbesẹ ati doju aabo ilẹ wa bolẹ ni."

Afeni lo sọ bẹẹ.

O kilọ pe ewu gidi lo wa nidii ohun to ṣẹlẹ yii, o ni awọn oniṣẹ ibi lo maa n lo iru ẹ lati huwa ọdaran kaakiri orilẹede.

O fidi ẹ mulẹ pe ileeṣẹ aṣọbode Ogun ti ko awọn oogun oloro naa fun ajọ NDLEA, ẹka Idiroko, fun itẹsiwaju iwadii ati bi awọn tọwọ ba yoo ṣe foju bale ẹjọ.