Wo ìdí tí ICPC fi mú dókítà tó ń tọ́jú El-Rufai àti bí aya rẹ̀ ṣe ń rọ Tinubu pé kó rántí àjọṣepọ̀

Oríṣun àwòrán, Presidency
Ajọ to n ri si ajẹbanu atawọn iwa ọdaran mi-in lorilẹede Naijiria, "Independent Corrupt Practices and Other Related Offences Commission'' (ICPC), ti fidi ẹ mulẹ pe loootọ loun gbe Ọjọgbọn Bello Abubakar, iyẹn dokita to n tọju gomina ipinlẹ tẹlẹ nipinlẹ Kaduna; Nasir El-Rufai, ju si atimọle.
Eredi bi wọn ṣe fọwọ ofin mu dokita naa ni ICPC ṣalaye pe o sọ ohun ti ko ri bẹẹ lẹyin ti kootu fi aaye silẹ fun El-Rufai lati lọ gbatọju nileewosan.
Ẹ o ranti pe El-Rufai ti wa ni gbaga ijọba lati oṣu keji ọdun 2026 lori ẹsun ajẹbanu atawọn mi-in tijọba apapọ n ba a fa.
Ki ni ICPC sọ pe o ṣẹlẹ gan-an?
Ninu atẹjade ti Agbẹnusọ ICPC, Okor Odey, fi sita lọjọ Iṣẹgun, ọjọ keje oṣu Keje ọdun 2026 yii ni wọn ti ṣalaye pe ajọ naa gbe El-Rufai lọ si abala aladaani ileewosan ijọba apapọ l'Abuja lọjọ Iṣẹgun naa fun itọju, gẹgẹ bi kootu ṣe fọwọ si i.
Wọn fi kun un pe aabo to peye lawọn pese lasiko ti El-Rufai lọ si ọsibitu naa.
Atẹjade naa tẹsiwaju pe awọn ẹṣọ ICPC to ba gomina Kaduna tẹlẹ naa lọ sileewosan huwa bii akọṣẹmọṣẹ, wọn kuro nibi ti ayẹwo dokita to n tọju jẹjẹrẹ naa yoo ti waye, ki wọn le fun oun ati El-Rufai lanfaani ati sọrọ ilera rẹ lai si idiwọ.
Wọn ni ṣugbọn niṣe ni El-Rufai ati dokita rẹ lo anfaani naa fun awọn ìṣe mi-in ti kootu ko fọwọ si fun wọn lati ṣe lasiko to yẹ ki wọn fi sọrọ ilera nileewosan ọhun.
Gẹgẹ bi ICPC ṣe wi, niṣe ni oludije fun ipo gomina ipinlẹ Kaduna ninu ẹgbẹ oṣelu ADC, Isa Ashiru Kudan, gbe fọto ara rẹ pẹlu awọn eeyan mẹta mi-in ti wọn jọ wa pẹlu El-Rufai lasiko to yẹ ko maa gba itọju nileewosan naa jade lori Facebook, ti wọn jọ jokoo ipade.
"Awọn fọto ati awọn ọrọ ti Isa Kudan gbe jade yẹn fi han pe wọn ṣeto abẹwo sile iwosan naa lati fi ṣe awọn ohun ti ile ẹjọ ati ICPC ro ni.
" Titẹ ofin kootu loju mọle kedere leyi."
Bẹẹ ni atẹjade ICPC naa ka lapa kan.
Wọn fi kun un pe El-Rufai ti ṣi anfaani ti ile ẹjọ fun un lo.

Oríṣun àwòrán, Others
Idi ti wọn fi mu Dokita Abubakar
Gẹgẹ bi ICPC ṣe wi, wọn fi ṣinkun ofin gbe Dokita Abubakar to jẹ dokita adani fun El-Rufai nitori irọ to pa lori onibaara rẹ to n tọju.
ICPC ṣalaye pe ko sẹni to fi to awọn leti tẹlẹ pe El-Rufai n lọ fun iru abẹwo sile iwosan yii, ati pe nigba ti dokita ajọ naa beere lọwọ El-Rufai boya nnkan kan n ṣe, niṣe lo ni alaafia ni.
Wọn ni El-Rufai sọ pe iyawo oun, Aisha El-Rufai toun naa jẹ ọkan lara awọn agbẹjọro oun lo ni koun kuku wa ri dokita adani, Ọjọgbọn Bello Abubakar.
Eyi n waye lẹyin ti ile ẹjọ giga ipinlẹ Kaduna kọ lati fun El-Rufai ni anfaani beeli gbigba, eyi to ti beere lẹẹmẹta ọtọọtọ bi ẹjọ ẹsun mẹsan-an ti ICPC ka si I lẹsẹ ṣe n lọ lọwọ.
Adajọ Darius Khobo ninu idajọ rẹ nigba naa sọ iwe to n tọka si ailera El-Rufai ti gomina tẹlẹ naa mu wa si kootu ko lẹsẹ nilẹ to lati fun ni anfaani beeli, nitori ile iwosan ijọba to wa l'Abuja ko gba iwe naa wọle.
Amọ bi kootu ko ṣee fi aaye beeli silẹ fun El-Rufai to, ile ẹjọ naa paṣẹ pe ki wọn jẹ ko maa ri dokita aladaani rẹ nigbakugba.
Kootu sọ pe anfaani tun wa fun wọn lati jẹ ki wọn mu un lọ sibudo ayẹwo tabi ileewosan to ba wu u ni Naijiria bi igbẹjọ rẹ ṣe n lọ lọwọ.
Iru anfaani naa si ni eyi ti wọn ni El-Rufai ti ṣilo yii, ti wọn si tori rẹ gbe dokita rẹ ju si atimọle.
Ẹhonu iyawo El-Rufai si Tinubu
Lọjọ Iṣẹgun ti iṣelẹ yii waye, ọkan ninu awọn iyawo El-Rufai torukọ rẹ n jẹ Asia El-Rufai, rọ Aarẹ Tinubu lati jẹ ki ọkọ oun gba itọju to peye.
Iyawo El-Rufai sọ pe iwa tijọba Tinubu n hu si ọkọ oun yii ko tọ rara, nitori El-Rufai pẹlu oun alara polongo ibo kiri fun Tinubu ni 2023.
Asia to sọrọ pẹlu iyawo keji gomina tẹlẹ naa, Aichatou, nilee wọn niluu Abuja, sọ pe awọn ko sọ pe ki aarẹ ma ba ọkọ awọn ṣe ẹjọ, amọ ki wọn jẹ ko jẹ anfaani ati ẹtọ to yẹ fun un bii ọmọ Naijiria.
"Aarẹ, mo polongo ibo fun ọ. Mo dide mo si lọ si gbogbo kọrọ ipinlẹ Kaduna nitori rẹ. Ọkọ mi duro ti ọ. Ṣe oun ti o yẹ fun ẹbi wa ree?
"Agbara wa lọwọ yin o, Aarẹ. Gbogbo ohun to n ṣẹlẹ yii ni yoo dopin bi ẹ ba sọrọ kan ṣoṣo ti yoo pari rẹ. A gbagbọ pe baba niyin, a si mọ pe ẹ le kaanu wa."
Bẹẹ ni Asia El-Rufai wi.
O tẹsiwaju pe ki wọn fun El-Rufai ni aaye beeli.
"To ba jẹbi, kootu ni yoo sọ ọ, to ba si jare, wọn yoo sọ ọ, ẹ jẹ ki kootu pinnu ohun ti yoo ṣẹlẹ"
Iyawo naa sọ pe ọkọ oun ni ẹjẹ riru, bi ko ba si ri itọju to peye gba, ko ma di pe iroyin aburu lawọn yoo gbọ latọdọ ijọba lọjọ kan.
Bakan naa ni Asia sọrọ nipa dokita ọkọ rẹ ti wọn fi si ahamọ.
"Wọn sọ fun wa pe aṣẹ lati oke wa sọ pe Ọjọgbọn Bello Abubakar ko le ri ẹnikankan laaarin wakati mẹrinlogun, ta lo paṣẹ latoke?"
"Awa naa fẹ sọrọ, a fẹ ki aye gbohun ẹnu wa, a fẹ idajọ ododo. Malam ko le ṣeto ijijagbara rẹ to ba wa ni ahamọ, ti ko si tun le ri awọn agbẹjọro rẹ daadaa."
Ki lo ṣẹlẹ ṣaaju to sọ El-Rufai ṣe to fi dero ahamọ
Ẹsun mẹsan-an to ni i ṣe pẹlu aṣilo ipo, ṣiṣe owo ilu mọkumọku, gbigbe akanṣe iṣẹ fawọn ti ko tọ si, kiko dukia jọ lọna eeru ka si ṣe bii pe owo to mọ ni (money laundering), ninawo ilu ni inakunaa fun ọdun mẹjọ to fi wa nipo gomina ipinlẹ Kaduna ni El-Rufai n koju lọdọ ijọba.
Ajọ ICPC sọ pe ẹsun rẹ tun kan didari owo ilu sibo miran ati ikuna lati tẹle ilana tijọba gidi n gba fi owo ilu ra nnkan elo.
Nasir El-Rufai loun ko jẹbi awọn ẹsun yii ṣaa, ohun to si maa n sọ ni pe oṣelu lasan lo wa nidii awọn ẹsun ti wọn fi kan oun yii, ki I ṣe pe oun ṣẹ ijọba lẹṣẹ kan.
ADC, ẹgbẹ El-Rufai sọrọ
Lori ọrọ El-Rufai yii, ẹgbẹ oṣelu ADC n fẹsun kan ijọba apapọ pe wọn n doju rẹ kọ ijiya ti ko tọ si i.
Ẹgbẹ ti El-Rufai n ti lẹyin naa sọ pe ijọba ko fun un lanfaani lati gba itọju fun ilera rẹ, wọn tun nawọ gan dokita rẹ, bẹẹ ni wọn huwa aitọ si iyawo rẹ.
Atẹjade ti Akọwe apapọ ADC, Bolaji Abdullahi, fi sita lọjọ Iṣẹgun ṣalaye pe Naijiria ti n wọ ipo amunisin lọ.
Wọn ni ilera El-Rufai lo n dinku to fi loun fẹ gbatọju nileewosan l'Abuja, ADC sọ pe bi kootu ṣe fun ni anfaani itọju to, ICPC tun taku pe afi kawọn da a pada si atimọle, wọn si tun nawọ gan dokita rẹ.
Gbogbo eyi ni wọn fi we iwa apaṣẹwaa ati ti ininilara.



























