Àwọn agbébọn mẹ́ẹ̀dógún ya wọ agboolé táwọn ilégbèé wà ní Ijebu-Ode, jí èèyàn mẹ́ta gbé lọ

Oríṣun àwòrán, Others
A kii jokoo nile ẹni fọrun wọ ni Yoruba maa n wi ṣugbọn owe yii ti n yipada bawọn afurasi agbebọn ṣe ti n yawọ ile awọn eeyan lati maa ji wọn gbe bayii.
Niṣe ni awọn afurasi agbebọn lọ ṣekọlu si agboole ile igbe kan ni ilu Ijebu-Ode, ipinlẹ Ogun, nibi ti wọn ti ji eeyan mẹta ti igbagbọ wa pe wọn jẹ ẹbi kan naa, gbe lọ.
Iroyin to tẹ wa lọwọ sọ pe awọn afurasi agbebọn ti iye wọn fẹ ẹ to mẹẹdogun ni wọn yabo ibugbe Ipojo Golden Estate to w ani agbegbe Oke-Eri ni nnkan bii aago meje irọlẹ pẹlu awọn ohun ija gidi.
Gẹgẹ bi iroyin, niṣe ni awọn agbebọn naa fipa wọ agbegbe naa, ti wọn si yawọ inu ile, gbe eeyan mẹta lọ.
"Ileeṣẹ ọlọpaa ti fi kun akitiyan wọn lati ṣawari awọn eeyan ti wọn ji gbe naa"
Wọn ni olori ile naa, Yesiru Badewa ko si nile lasiko ti iṣẹlẹ naa fi waye bo ṣe jẹ pe o lọ fun iṣẹ oojọ rẹ.
Badewa nigba to n ba awọn awọn akọroyin kọminu lori iṣẹlẹ naa, bo ṣe jẹ pe ọkan ninu awọn eeyan ti wọn ko lọ ni ara rẹ ko ya.
O wa parọwa sawọn ọmọ Naijiria lati ṣe iranwọ fun bi wọn ṣe le ṣawari awọn eeyan naa nitori o ṣeeṣe ki ẹni ti ara rẹ ko ya naa tun le si nigba to b awa ni akata awọn ajinigbe ọhun.
Agbẹnusọ ọlọpaa Ogun, Oluseyi Babaseyi to fidi iṣẹlẹ naa mulẹ sọ pe ileeṣẹ ọlọpaa ti pọn kun akitiyan wọn lati ṣawari awọn eeyan ti wọn ji gbe naa ati lati nawọ gan aw.on afurasi to huwa naa.
Bakan naa lo rọ awọn eeyan ibugbe naa lati ṣe suuru, ki wọn fi ọkan balẹ, pe iṣẹ ti n lọ lati tunbọ da aabo bo ẹmi ati dukia awọn eeyan ni ipinlẹ Ogun.
"Ileeṣẹ ọlọpaa mọ nipa iṣẹlẹ to waye ni ibugbe Ipojo Golden Estate, Oke-Eri, Ijebu-Ode, a si ti bẹrẹ igbesẹ lati pọnkun aabo agbegbe naa ati lati nawọ gan awọn to ṣiṣẹ ibi naa."



























