Ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa ikọ̀ ọlọ́pàá VCRU tuntun, ìdí fún ìdásílẹ̀ rẹ̀ àti iṣẹ́ àwọn ọlọ́pàá náà

Oríṣun àwòrán, Nigeria Police Force/X
Ọga agba ọlọpaa Naijiria, Olatunji Disu, ti ṣe ifilọlẹ ikọ ọlọpaa tuntun ti wọn pe ni VCRU, eyi ti yoo maa gbogun ti iwa ọdaran lawujọ.
Ọga ọlọpaa ṣe ifilọlẹ naa lasiko to bawọn lọgalọga ọlọpaa ṣepade pọ niluu Abuja lana ọjọ Iṣẹgun ọjọ karun un oṣu Karun un yii.
Disu ni ifilọlẹ yii jẹ ọna lati ṣe akanṣe iṣẹ atunṣe ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria.
''Inu mi dun lati kede ifilọlẹ atunṣe ileeṣẹ ọlọpaa orilẹede Naijiria.
A ti ṣe atunṣe ọna ti a n gba lati gbogun iwa ọdaran lawujọ ni Naijiria.
Ikọ ileeṣẹ ọlọpaa to n ri si ohun ija oloro ati ẹka to n ri si lilo ọgbọn inu ni a papọ si ikọ VCRU bayii,'' Disu lo sọ bẹẹ.
''A ko ni ran ikọ ọlọpaa VCRU jade lori ahesọ ọrọ lasan an''
Oga ọlọpaa Naijiria ni igbesẹ yii ko wa lati yi orukọ ileeṣẹ ọlọpaa pada si daadaa, bi ko ṣe wiwa ọna tuntun lati koju iwa ọdaran.
O ni ikọ ọlọpaa VCRU niṣe pẹlu bi ileeṣẹ ọlọpaa yoo ṣe maa gbogun ti iwa ọdaran ni Naijiria.
Ọgbẹni Disu sọ pe gbogbo ọlọpaa ti yoo maa ṣiṣẹ pẹlu ikọ VCRU lo ti gba idanilẹkọọ lori ọgbọn inu, ẹtọ ọmọniyan ati lori bi wọn yoo ṣe maa ṣe si araalu lẹnu iṣẹ.
Disu ni gbogbo awon ọlọpaa naa ni wọn ti gba idanilẹkọọ lọna igbalode.
Ọga ọlọpaa Naijiria sọ pe ''a ko ni ran ikọ ọlọpaa VCRU jade lori ahesọ ọrọ lasan an.
A ko si ni lo ikọ ọlọpaa yii lati ṣegbe lẹyin ẹnikan, iwadii ti a ba ṣe la o maa fi ran wọn jade lọ ṣiṣẹ.
Ileesẹ ọlọpaa yoo si maa ṣe agbeyẹwo bawọn ikọ ọlọpaa naa ṣe n ṣe loorekoore.''
Ọga ọlọpaa wa paṣẹ fun gbogbo awọn kọmiṣọna ọlọpaa ipinlẹ lati gbaruku ti ikọ ọlọpaa VCRU lawọn ipinlẹ wọn.
Bakan naa tun ni ọga ọlọpaa sọ pe awọn araalu ni lati mọ nipa ikọ ọlọpaa yii ati nnkan ti wọn wa fun.




























