Àjọ tó ń ri sí ìwà jẹgúdújẹrá (ICPC) kẹ́fín N450bílíọ̀nù tí wọ́n ná lọ́nà àìtọ́ nínú àbá ìṣúná

aworan

Oríṣun àwòrán, ICPC NIGERIA/FACEBOOK

Published

Ajọ to n gbogun ti iwa jegudujera ni Naijiria, ICPC ti kede pe awọn aisedeede wa ninu isuna ọdun 2021 ati 2022 ni owo to to bilionu irinwo naira (400bn) ni wọn fikun awọn ẹto isuna ọdun naa.

Ajọ naa ni awọn ile iṣẹ ati awọn ẹka ile iṣẹ ijọba lo jebi ẹsun naa, nigba ti N49.9 bilionu ni wọn yo sọtọ lati san fun awọn oṣiṣẹ ti ko si lẹnu iṣẹ rara.

Alaga ajọ ICPC, Ojogbon Bolaji Owasanoye so eyi lakoko ipade ibaraẹnisọrọ pẹlu awọn asofin agba to n ri si ẹto isuna bi wọn ti n gbaradi lati beere si ni jiroro lori aba ẹto isuna ọdun 2023.

Owasanoye sọ pe ajọ oun ṣayewo ni kikun awọn owo ti ijọba ya soto fun awọn eka ijọba koọkan ti awọn di awọn alafo iwa ibaje ati inawo ijọba lori awọn ẹto akanṣe ti ko si lori iwe.

aworan

Oríṣun àwòrán, ICPC NIGERIA/FACEBOOK

Owasanoye ICPC ni: “N300bn ni ijọba apapọ yoo ti sofo lori awọn iṣẹ akanṣe ti wọn fi sinu isuna ọdun 2021 ati N100bn fun isuna ọdun 2022 ti ajọ ohun si gba pada lọwọ awọn ajọ naa.

Oro ile igbimọ asofin lati ṣe ayẹwo aba isuna tirilionu okandinlogun le die naira ti ọdun 2023 eyi ti aare Muhammadu Buhari n gbe bo.

Owasanoye nii ajọ ohun man wogile awọn akanse ise ti awọn ri wi pe wọn gbe jade lona aito ati awọn akanse iṣẹ ti ko si lori iwẹ ijọba .

Alaga Igbimo naa, Solomon Olamilekan Adeola so wi pe alekun yoo de ba owo iṣẹ ṣiṣe ti ajọ ICPC ninu ẹto isuna odun 2023.