Agbébọn jí ajagunfẹ̀yìntì àti ìyàwọ rẹ̀ gbé ní Katsina

Ọgagun Rabe Abubaka lasiko to wa lẹnu iṣẹ

Oríṣun àwòrán, AFP via Getty Images

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Awọn agbesunmọmi ti ji ọkunrin kan to jẹ ọgagunfẹyinti nileeṣẹ ologun Naijiira, Maj Gen Rabe Abubaka ati iyawo rẹ gbe lọ lapa ariwa Naijiria.

Ọgagun Rabe Abubakar to jẹ agbẹnusọ fun ileeṣẹ ologun Naijiriala larin ọdun 2015 si ọdun 2017 ni wọn ji gbe lasiko ti wọn kọlu ọkọ rẹ lasiko to n rinrinajo lọ si ipinlẹ Katsina.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọmọ ogun, Michael Onoja sọ fun BBC pe iṣẹ ti bẹrẹ lati tọpinpin awọn to jii gbe ki wọn le doola rẹ.

Ijinigbe yii n ṣapẹrẹ bi eto aabo ṣe mẹhẹ to ni Naijiria lasiko yii, paapaa ni Ariwa Naijiria.

Apa ariwa yii lawọn agbesunmọmi, ti ijọba n pe ni "janduku" ti mu ijinigbe gẹgẹ bii iṣẹ.

Bi wọn ṣe n ji ọmọ eeyan gbe fun owo itusilẹ naa ni wọn n ji maalu gbe ti wọn tun n kọlu awọn agbẹ ninu oko wọn.

Yatọ si awọn ti ijọba n pe ni janduku yii, awọn alakatakiti ẹsin naa ko gbẹyin nibẹ.

Iroyin ni ọkan lara awọn ibudo awọn alakatakiti ẹsin Islam ni ileeṣẹ ologun Amẹrika kọlu lọjọ ọdun Keresimesi ninu oṣu Kejila ọdun 2025.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ipinlẹ Katsina jẹ ọkan gboogi lara awọn ipinlẹ ti iṣẹlẹ ijinigbe ati igbesunmọmi ti gbọngbọn julọ ni Naijiria.

Yatọ si Katsina, ipinlẹ Zamfara, to fẹgbẹkẹgbẹ pẹlu Katsina ati Sokoto naa n koju ikọlu awọn agbesunmọmi.

Gbogbo igbiyanju awọn eeyan agbegbe naa lati dunadura pẹlu awọn ọdaran naa lo ti fori ṣọpọn.

Ni iha ijọba, o ni oun n gbiyanju lati fopin si tabi din ijinigbe ku ni Naijiria amọ pupọ ninu igbiyanju ijọba ni ko so eso rere.

Lọwọ yii, ko tii si ẹgbe kankan to kede pe awọn lo wa nidi ijinigbe ajagunfẹyinti yii, awọn amọlẹbi ọgagun naa ṣi ti n duro de awọn agbesunmọmi ọhun lati kan si awọn lati bere ohun ti wọn n fẹ.

Awọn ileeṣẹ iroyin abẹle kan sọ pe ayẹyẹ igbeyawo ni ajagunfẹyinti naa n lọ ki wọn to kọlu ọkọ ayọkẹlẹ rẹ.

A gbọ pe awakọ Abubakar moribọ ninu ikọlu naa bo tilẹ jẹ pe o fara gbọta ibọn.

Iṣẹlẹ yii lo n waye lẹyin ikọlu awọn agbebọn si abule Kiliya to wa ni ijọba ibilẹ Dutsinma nipinlẹ Katsina, nibi ti wọn ti ṣekupa eeyan mẹrindinlogun.