A ti pa púpọ̀ nínú àwọn agbésùnmọ̀mí tó kọlu ilú márùn- ún -Iléeṣẹ́ ọmọ ogun

Awọn ikọ agbesunmọmi kan, ẹni kan gbe ibọn dani ninu wọnninu ọkọ .

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Lọjọ Abamẹta, ọjọ kẹrin oṣu Keje ọdun 2026 yii ni awọn agbebọn kọlu awọn awọn agbegbe kan lorilẹede Mali, titi kan aaye tawọn ologun wa, amọ ileeṣẹ ologun ibẹ ti ni awọn pada pa pupọ ninu wọn.

Ninu atẹjade ti ileeṣẹ ologun Mali fi sita ni wọn ti ṣalaye, pe alaafia ti jọba ni ilu marun-un ti awon agbesunmọmin naa dojukọ.

Awọn ilu naa bi wọn ṣe darukọ wọn ni Alguel-Hoc, Anéfis, Goa to wa ni ni Ariwa Mali, Kenioroba to wa ni Guusu ti ko si jinna si olu ilu ti i ṣe Bamako ati Sévaré to wa ni Aarin gbugbun Mali.

"Ni Sévaré, agbesunmọmi ogún (20) ti wọn wa lori alupupu atawọn to wa ninu ọkọ ogun ni a pa, a si tun pa awọn mẹfa ni Gao."

Bẹẹ ni apa kan atẹjade naa wi.

Amọ wọn ni ọkan lara awọn agbefọba ba iṣẹlẹ yii lọ, nigba ti awon mẹrin mi-in farapa .

Ẹgbẹ to n pe fun ipinya ni Mali, Tuareg, ti wọn yapa latọdọ awọn Azawad Liberation Front (FLA), sọ pe awọn lawọn wa nidii mẹta ninu awọn agbegbe ti ikọlu naa kan, bo tilẹ jẹ pe awọn ologun Mali atawọn ikọ lati Russia wa nibẹ.

Bawo ni ikọlu ọjọ Satide naa ṣe waye?

Gẹgẹ bi ileeṣẹ ologun Mali ṣe ṣalaye, nnkan bii aago marun-un idaji ọjọ Satide naa ni iro ikọlu ọhun bẹrẹ si i dun.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ikọlu naa waye lẹyin oṣu meji ti ikọ alakatakiti ti wọn ni wọn n ba Al Qaeda ṣe, pẹlu awọn Tuareg kọlu Mali ti wọn si pa minisita eto aabo orilẹede naa.

Awọn ilu ti wọn kọlu lojọ Abamẹta naa ni Gao, Anefis Aguelhok, Sevare ati Kenieroba nitosi Bamako.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, ọgba ẹwọn to wa ni Kenioroba ni awọn alatako naa gbiyanju lati kọlu, pẹlu erongba lati ṣi awọn alatako ijọba to wa nibẹ silẹ, ṣugbọn awon ologun ko jẹ ki wọn ri eyi ṣe.

Awọn olugbe agbegbe Gao kan ṣalaye pe ìró ibugbamu to lagbara ni awon n gbọ lasiko ikọlu naa nitosi ibudo awon ologun kan.

Tẹ o ba gbagbe, orilẹede Mali ti Ọgagun Assimi Goita n dari ti n koju ikọlu awọn agbesunmọmi tipẹ lati ọdọ awọn Al-Qaeda ati Daesh.

Bakan naa ni awọn Tuareg to wa ni ẹkun Ariwa Mali n pe fun iyapa ti wọn si n daamu ilu naa.

Bo tilẹ jẹ pe orilẹede Russia n ṣeranwọ fun wọn lẹka aabo, nnkan ko ti I fararọ.

Bakan naa ni awọn alamuleti Mali, iyẹn Burkina Faso ati Niger naa n koju igbesunmọmi, gẹgẹ bo ṣe n ṣẹlẹ ni Naijiria naa lọwọlọwọ.