Kókó ọ̀rọ̀ tí Akeem, ọkọ Sisi Alagbo sọ rèé lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ tó mú kí ẹnu ayé kun òun àti aya rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Sisi Alagbo
Bi ẹlẹjọ ba ti mọ ẹjọ rẹ lẹbi, ko ni I pẹ lori ikunlẹ ni ọrọ fidio ibalopọ gbajumọ alagbo, Eniola Fagbemi ati ọkọ rẹ, Adesola Akeem da bayii.
Bi iyawo ṣe n tọrọ aforiji ni ọkọ naa si tun jade bayii pe oun gba gbogbo ẹbi fọnran ibalopọ to lu jade ọhun.
Loju opo Facebook rẹ ni Akeem ti n bẹbẹ l'Ọjọbọ, nibẹ lo ti tọrọ aforiji lọwọ gbogbo eeyan fun fidio ibi to ti n ba Sisi Alagbo ati obinrin miran ni ajọṣepọ, to gbode kan lọjọ Aje ọsẹ yii.
"Pẹlu gbigba gbogbo ẹbi ohun to ṣẹlẹ ati ironupiwada ni mo fi tọrọ aforiji lọwọ awọn ẹbi mi, awọn ọrẹ, awọn ti a jọ n ṣowo pọ, awọn olori ẹsin, awon ololufẹ ati gbogbo Naijijriia pata lori iṣẹlẹ ibalopọ to lu jade.
"Mo gba pe mo ja yin kulẹ, mo gba idojutini ati ikaramasiki ti iṣẹlẹ yii mu ba yin, mo si gba gbogbo ẹbi ohun ti mo ṣe."
Bẹẹ ni ọkọ Sisi Alagbo bẹbẹ lori iṣẹlẹ to sọ ọ di gbajumọ ojiji naa.
"Mo maa yi iwa pada lati isinyi lọ"
O fi kun un pe oun ti pinnu lati yi iwa oun pada bayii, oun yoo maa ṣiṣẹ tọ iwa ọmọluabi ni kọrọ ati ni gbangba lati isinyin lọ.
Bi Akeem ṣe tọrọ idariji lọwọ awọn eeyan naa lo tun ṣe Astagfirulah, eyi to fi tọrọ idariji lọwọ Ọlọun Allah.
O ni Ọba to n foriji eeyan tan ti yoo tun kẹ onitọhun ni Allah, ko ma ṣai foriji oun fun aṣiṣe to kari aye yii.
Tẹ o ba gbagbe, Ọjọru ni Sisi Alagbo funra ẹ ti kọkọ bẹbẹ lori ayelujara, to ni oun ko le sun mọ nitori idaamu ọkan ati itiju ti fidio naa ti ko ba oun.
Ọkọ paapaa sọ bi ohun gbogbo ko ṣe ri bo ṣe yẹ mọ ninu ile latigba ti wahala yii ti bẹrẹ.
Ṣugbọn ọpọ eeyan lo n sọ pe ẹbẹ ti wọn n bẹ kiri ko kan aye, wọn ni ohun ti wọn jẹ lo yo wọn.
Awọn ẹlomi-in n sọ pe awọn ni wọn ni ihooho won ti won fi ṣẹṣin, ẹbẹ ti wọn n bẹ ko s iyi fidio to ti jade pade.
Wọn ni eegun to ti jade ti kuro ni ai wo o.
Kí ló dé tí ẹnu fi ń kun Sisi Alagbo lórí ayélujára àti ọ̀rọ̀ tó sọ lórí rẹ̀?

Oríṣun àwòrán, Sisi Alagbo
Gbajumọ obinrin to n ta agbo lori ayelujara, Eniola Fagbemi, ti ọpọ mọ si Sisi Alagbo, ti sọrọ aforijin lọwọ awọn olofẹ rẹ lẹyin ti fidio ibalopọ rẹ lu sita lori ayelujara.
Ninu fidio naa ni ohun ati ọkọ rẹ Adesola Hakeem ti n ba obinrin mii lajọṣepọ, ti oun naa si wa lori ibusun pẹlu wọn ni ihooho.
Ọjọ Aje ọsẹ yi ni fidio naa kọkọ fa ori ayelujara ya, eyii ti ọpọ araalu ti bu ẹnu atẹ lu u.
Fagbemi sọ nipa nnkan to n dojukọ lẹyin ti fidio ọhun lu sita, o ni iṣẹlẹ naa ti gba orun loju oun fun ọpọ ọjọ, koda oun lo oogun orun amọ awọn oogun naa ko ṣiṣẹ.
Nigba to n sọrọ loju opo Facebook rẹ, o ni "Mo gba pe mo ti ṣe aṣisẹ, mo si tọrọ aforinjin pẹlu gbogbo ọkan mi lori fidio to n mi ori ayekujara titi.
"Mo tọrọ aforin lọwọ gbogbo awọn ti mo ja kulọ.
"Asiko yii jẹ asiko to lagbara fun mi, mo si bẹbẹ fun aforinjin lọwọ Ọlọrun atawọn ololufẹmi, ẹ jọọ ẹ jẹ ka kuro lori ọrọ yii nitori ori ayelujara naa ni mo ti n ri atilẹyin to n fun mi lounjẹ. Ẹ jọọ ẹ ma sọrọ abuku si mi nitori mo n la ọpọ nnkan kọja lọwọ yii."
Sisi Alagbo tẹsiwaju pe "Mi o le jẹun, bẹẹ ni mi o le sun fun ọpọ ọjọ, koda oogun orun ti mo lo ko ṣiṣẹ fun mi mọ. Ẹ jọọ ẹ darijin mi gbogbo Eniyan.
"Ẹ jọọ ẹ darijin mi, mi o fẹ ṣe ara mi leṣe, okun kekere ti mo ni ree."
Taa ni Sisi Alagbo?

Oríṣun àwòrán, Sisi Alagbo
Fagbemi 'Sisi Alagbo' di gbajumọ ori ayulujara lẹyin to bẹrẹ si n ta agbo loju opo Facebok rẹ.
O sọ lasiko naa pe iṣẹ iya-iya oun ni iṣẹ agbo ṣiṣẹ ati tita, oun si n ta agbo kaakiri Naijiria ati titi de orilẹede China ati Qatar.
Okiki rẹ tunbọ kan si lasiko to pade agbabọọlu Super Eagles, Victor Osimhen lorilẹede Morocco lasiko idije 2025 Africa Cup of Nations.
Ninu fidio rẹ pẹlu Osimhen, o ṣafihan bo ṣe kunlẹ fun, fidio ọhun si mi ori alujara titi.
Ninu atẹjade kan loju opo Facebook rẹ lọdun 2023, o ni bo tilẹ jẹ pe oun n ta agbo, oun kii mu ọti.
O ni ọmọlẹyin Kristi loun lọdun naa lọhun amọ Musulumi ni ọkọ ti oun fẹ.
Sisi Alagbo sọ siwaju si "Atapata dide ọmọ alagbo lasan ni mi, mo gba Ọlọrun gbọ, mo gba Jesu Krisiti gbọ, mo si gba ẹmi mimọ gbọ."
O sọ lọdun naa lọhun pe agbo oun wa fun awọn obinrin to n wo oju Ọlọrun fun ọmọ, to fi mọ agbo to n fun ọkunrin lagbara ninu iyẹwu.




























